Ezekiel 31:12-14

12àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì aláìláàánú jùlọ ké e lulẹ̀, wọn sì fi kalẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣubú sórí òkè àti sí gbogbo àárín àwọn òkè; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí ó ṣẹ nà sílẹ̀ ní gbogbo àlàfo jíjìn ilẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé jáde kúrò ní abẹ́ ìji rẹ̀ wọn sì fi sílẹ̀. 13Gbogbo àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ni orí igi tí ó ṣubú lulẹ̀ náà, gbogbo àwọn ẹranko igbó wà ní àárín ẹ̀ka rẹ̀. 14Nítorí náà kò sí igi mìíràn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tí ó lè fi ìgbéraga ga sókè fíofío, tí yóò sì gbé sókè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ. Kò sí igi mìíràn tí ó ní omi tó bẹ́ẹ̀ tí ó lè ga tó bẹ́ẹ̀; gbogbo wọn ni a kádàrá ikú fún, fún ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ní àárín àwọn alààyè ènìyàn, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ọ̀gbun ní ìsàlẹ̀.

Copyright information for YorBMYO